B’eru ese re ba nwo o lorun | If you are tired of the load of your sin |…

0
CACGHB 875

10.8.10.8. & Ref.
E wa sodo mi, gbogbo enyin ti n sise, ti a si di eru wiwo le lori, Emi o si fi isimi fun nyin. Matt. 11:28

1. B’eru ese re ba nwo o lorun,
Pe Jesu wole okan re;
B’o nd’aniyan isoji okan re,
Pe Jesu wole okan re,

Le ‘yemeji re sonu,
Ba Oluwa re laja;
Si okan re paya fun,
Pe Jesu wole okan re.

2. Bi o ba nwa iwenumo kiri,
Pe Jesu wole okan re;
Omi ‘wenumo ko jina si o,
Pe Jesu wole okan re.

3. B’igbi wahala ba ngba o kiri
Pe Jesu wole okan re;
B’afo ba wa ti aye ko le di,
Pe Jesu wole okan re

4. Bi ore t’o gbekele ba da o
Pe Jesu wole okan re;
On nikan ni Olubanidaro,
Pe Jesu wole okan re,

5. B’o nfe korin awon olubukun
Pe Jesu wole okan re,
Bi o nfe wo agbala isimi,
Pe Jesu wole okan re.
‘Yemeji mi ti fo lo,
Mo b’Olorun mi laja,
Mo s’okan mi paya fun,
Jesu ti wole okan mi.
Amin.